Ìpínlẹ̀ Kano yóò máa ṣe àtìlẹ́yìn fún ìtẹ̀síwájú ohun gbogbo tó jẹ mọ́ ẹtọ ọmọnìyàn ni ìpínlẹ̀ náà.
Eléyìí di sísọ láti ẹnu onídàájọ àgbà àti Komisọ́na fún eto ìdájọ ìpínlẹ̀ kano, Barr. Haruna Isa Dederi níbi ti o ti n sojú fún Gómìnà Abba Kabir Yusuf níbi ìsíde ipele kẹrin àjọ United Nations UPR ibaṣepọ wọn pẹlu alẹ́nulọ́rọ̀ ti àjọ Inter-Ministerial Committee (IMC) gbékalẹ̀ ní Tahir Guest Palace, ìlú Kano.
Látàrí pe ipinle Kano fi ọ̀wọ̀ fún ẹtọ ọmọnìyàn, Ó sọ pé, ìpínlẹ̀ Kano yóò máa tẹ̀síwájú lati máa ṣe àtìlẹ́yìn fún ìgbésẹ̀ yòówù tó faramọ ìgbékalẹ̀ àti àtúnṣe ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn.
Ó wá sọ fún àwọn olùkúpa to wá láti orílẹ̀-èdè yí pé ki wọ́n fi ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ níbi ètò náà sí ojúṣe kí ó leè jẹ àjẹmönú fún ìpínlè wọn ati Nàìjíríà ní àpapọ̀.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply