Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdájọ́ ilé-ẹjọ́: Ganduje pè fún àlàáfíà

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 191

Alága, ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress (APC), Alhaji Abdullahi Ganduje, ti rọ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Kano láti fara balẹ̀, tí ó sì ń fi dáwọn lójú pé àyípadà rere yóò bá kátàkárà.

O n fi idi eleyi mulẹ ni Ọjọọru, ni Abuja, nigba ti o n fesi si idajọ ile-ẹjọ lori idibo gomina ipinlẹ Kano, tí o gba Dokita Yusuf Gawuna, wọle ninu idibo gomina oṣu kẹta gẹgẹ bi ẹni ti wọn yan. Adajọ Oluyẹmi Akintan-Osadebay ni ẹni ti o da ẹjọ naa.

Ẹgbẹ oṣelu APC ti koju ikede Gomina Abba Kabir Yusuf, ti ẹgbẹ oṣelu New Nigeria People’s Party (NNPP), gẹgẹ bi ẹni ti o jawe olubori ninu idibo gomina ipinlẹ Kano, ni ọjọ kejidin-logun, oṣu kẹta.

Ganduje,  Gawuna ati gomina ipinlẹ naa, Sẹnetọ Kabir Gaya, wa rọ awọn eniyan ipinlẹ Kano lati wa lalaafia.

O wa ṣapejuwe idajọ yii gẹgẹ bii afihan ododo ifẹ awọn eniyan ipinlẹ Kano, ti o si dupẹ lọwọ awọn Adajọ, awọn adari APC ati awọn oni karakata ni ipinlẹ naa fun atilẹyin wọn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button