Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé iṣé Ìjọba Ti Ìpínlẹ̀ Kwara Se Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Fún Awọn Àgbẹ̀ Nípa Ọ̀gbìn Ẹ̀gẹ́.

0 218

Ó lẹ ní àádọ́ta àwọn àgbẹ̀ àti àwọn ènìyàn tí ó kópa nínú ìdánilékòó nípa ẹ̀gẹ́ gbin gbìn èyí wáyé láti mú ìdàgbàsókè bá ètò ounjẹ ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ilé iṣé Ìjọba fún ètò ọgbin àti oúnjẹ ní o ṣe agbáterù ètò náà àti ìbáṣepọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara, ìdánilékọ̀ọ́ náà wáyé ni ọfisi ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara fún ètò ògbìn ati ounjẹ.

Ní gbà tí ó ń sọ̀rọ̀ níbi ìdánilékọ̀ọ́ náà alàkóso fún ilẹ iṣé ìjọba lórí ọ̀rọ̀ ètò ọ̀gbìn, Ọ̀mọ̀wé Aliyu Issa Kabir,  ní kókó ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà ni kí ìdàgbàsókè bá lè bá ètò ounjẹ àti láti ṣe ìrànlọ́wọ́ iṣé fún àwọn ọ̀dọ́ àti àwọn obìnrin lápapọ̀.

Ó ní irú ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yìí ti wáyé nínú ọdún nípa ẹwà soya ati Isu.

Kabir ni yóò tún jẹ ànfààní fún àwọn ènìyàn láti rí iṣé ṣe àti láti bẹ̀rẹ̀ iṣé fún ara wọn láì ṣe wí pé wọ́n dúró dé ènìyàn.

Ó  wà rọ àwọn Akọ́pa lati tan èrè ọ̀gbin wọn ni owó kékere fún àwọn ará ìlú ko ba lè jẹ ìrànwọ́ fún ìjọba àti ara ìlú.

Alága àwọn ẹgbẹ́ àgbẹ̀ ni Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Onímọ̀ ẹrọ Gabriel Fasaanu dupẹ lọwọ ìjọba fún ìdánilékọ̀ọ́ náà .

Ó wà rọ ìjọba àpapọ ati ti ìbílẹ̀ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ láti àtìlẹ́yìn fún àwọn àgbẹ̀ ni gbogbo ọ̀nà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button