Take a fresh look at your lifestyle.

Arábìnrin àkọ́kọ́ Nàìjíríà gbàlejò àwọn ìyàwó ọ̀gá elétò ààbò

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 207

Iyawo aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Olurẹmi Tinubu sọ pe ki awọn ọmọ Naijiria maa jẹ ki bi igba ṣe ri bawọn ninu jẹ nitori pe ireti ṣi wa, ki wọn ma sọreti nu.

O n sọ eleyii ni ọjọ iṣẹgun nigba ti o n gbàlejò àwọn ìyàwó ọ̀gá elétò ààbò ati Ọga agba fun awọn Agbofinro, ti iyawo ọga agba fun awọn oṣiṣẹ aabo ati aarẹ, aabo ati ẹgbẹ awọn iyawo agbofinro, Iyaafin Oghogho Musa.

Arábìnrin àkọ́kọ́ wa n fi da wọn loju pe ijọba aarẹ Bola Tinubu  n sa gbogbo agbara rẹ lati pẹtu si inira iyọkuro owo adinku epo ilẹ titi ti anfaani rẹ yoo fi jade.

O sọ pe iṣẹ akanṣe oun, ti o jẹ Idasilẹ Atunṣe Ireti, tun n ṣatilẹyin fun ijọba lori rẹ, idi niyi ti o fi n pe fun atilẹyin àwọn ìyàwó ọ̀gá elétò ààbò.

Arábìnrin àkọ́kọ́ tun wa pinnu pe Idasilẹ Atunṣe Ireti, yoo to kan awọn opo awọn ọmọ ogun to fi ẹmi wọn lelẹ fun orilẹ-ede.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button