Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu buwọ́lu yíyan adarí tuntun fún NIMC, DTAC

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 199

Ààrẹ Bọla Tinubu ti pàṣe kí ìsinmi ìfẹ̀yìntì alàádọ́rùún ọjọ́ lẹ́nu iṣẹ́ Adarí gbogbogbòò ìgbìmọ̀ tó ń ṣàkóso ìdánimọ̀ lórílẹ̀-èdè (NIMC), Aliyu Aziz, bẹ̀rẹ̀ ní kíá mọ́sá láti ọjọ́ kẹrìnlé-lógún, oṣù kẹjọ 2023, léyìí tí yóò padà yọrí sí ìfẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́ ní ọjọ́ kẹrìnlé-lógún, oṣù kọkànlá, 2023.

Ààrẹ ti wa buwọlu yiyan Bisoye Coker-Odusote lati jẹ adari gbogbogbooo fidihẹ ti ìgbìmọ̀ tó ń ṣàkóso ìdánimọ̀ lórílẹ̀-èdè fún àádọ́rùún ọjọ́ , leyii ti yoo bẹrẹ ni láti ọjọ́ kẹrìnlé-lógún, oṣù kẹjọ 2023, lẹyi eyi ti yoo ṣẹṣẹ wa bẹrẹ ọdun mẹrin rẹ gẹgẹ bii adarí gbogbogbòòọjọ NIMC, bẹrẹ ni ọjọ́  kẹrìnlé-lógún, oṣù kọkànlá, 2023.

Lafikun, ààrẹ Tinubu ti buwọ́lu yíyan Yusuf Yakub lati jẹ Adarí Directorate of Technical Aid Corps (DTAC).

Eleyii waye latari opin asiko Adari DTAC tẹlẹ , Dokita Pius Osunyikanmi.

Oludamọran pataki fun aarẹ lori  ibaraẹnisọrọ ati ipilongo, Ajuri Ngelale  fidi eyi mulẹ ninu ọrọ rẹ kan, sọ pe iṣẹ bẹrẹ ni kia mọsa lẹyin yiyan yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button