Take a fresh look at your lifestyle.

Adeleke Gba Ọ̀kan Lára Àwọn Ìràwọ D’Tigress, Olawuyi Ní Alejò

0 458

 

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Sénétọ̀ Ademola Adeleke gba ọ̀kan lára ìràwọ ikọ̀ D’Tigress, Adenike Olawuyi. ní àlejò ni ìlú Òsogbo.

Adenike Olawuyi jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Osogbo, ó ń seré fún Kílọ̀bù ti wọ́n n pè ni Ratgeber ni orílè-èdè Hungary, ó tún fakọ yọ fun orílè-èdè rẹ̀ Nàìjíríà nínú ìdíje tó tẹnu bọpo ti bọ́ọ̀lù a jù sápẹ̀rẹ̀ ọdún 2023 FIBA AfroBasket Championship to wáyé ni Kigali.

Gómìnà àti akọwé fún ìjọba ìpínlẹ̀ osun,Teslim Igbalaye, ki kú oríire,

Gómìnà Adeleke gba ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún àti akọ́nimọ̀ọ́gbá rẹ̀ ni ìyànjú láti mura sí, kí wọ́n túbọ ni afojusun nitori ibi gíga tí wọn n nlọ.

“Inú mi dun lati gba ọ́ lálejò loni. Ó jẹ ìyí fún mi láti ri ọ̀dọ́ àti ẹni to ni akitiyan fun ọjọ́ ọ̀la rere tó wà láti ipinlẹ Ọ̀sun. Ẹrí ni èyí pé ìmúra sí iṣẹ́, ìfẹ́ sí nǹkan ti a ń se àti ìtẹra mọ́ iṣẹ́, ènìyàn leè se ọpọlọpọ gbogbo nǹkan”.
“Máa tẹ̀ síwájú . O ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni”..

“Nǹkan ti mo ṣèlérí ni wí pé ere ìdárayá yóò lo sí ibi gíga, a o sì ṣe àwárí ọ̀pọlọpọ̀ awọn ìràwọ̀ fún ipinle osun.”, o parí pẹ̀lú eyi.

Olawuyi àti àwọn akegbẹ rẹ̀ borí ni ìgbà ẹ̀kẹ́rin ni ile Adulawo ni Ligali pelu ayo
84-74.ti wọn fi lù iko Senegal.

Jíjá ewe olubori náà túmọ sí pé wọn o tun soju fún ilẹ Áfíríkà ni idije agbaye Olympics ti odun 2024 aju bọọlu sinu àpẹẹrẹ ti àwọn obinrin.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button