Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ pè fún aṣòfin obìnrin láti rọ́pò Gbajabiamila

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 223

Ẹgbẹ́ alájọṣepọ̀ kan, Àwọn obìnrin tí ń gbóbìnrin nígbùnwọ́ dókè, ti rọ ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives  (APC), ikọ̀ ìpínlẹ̀ Eko, ń gbèrò láti fi aṣojú obìnrin rọ́pò Fmi Gbajabiamila ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojú.

Ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Ìyáàfin Bọlanle Oyeyẹmi, pe ìpè yìí nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ kan,ní Ọjọ́ọ́rú, ní Eko.

Oyeyemi sọ pe irọpo yii ṣe pataki nitori yiyan Gbajabiamila, aṣoju ile igbimọ aṣoju to ṣẹṣẹ kuro, gẹgẹ bi ọga agba fun awọn oṣiṣẹ aarẹ Bọla Tinubu.

Ó ní ìgbàgbó nínú ìlànà APC, pé ẹgbẹ́ náà ní fífi àwọn obìnrin sínú òṣèlú lọ́kàn.

Aarẹ ni ẹgbẹ naa ti fa Aṣofin Jamila Mu’azu-Olukosi lelẹ gẹgẹ bi ẹni tí yóò rọ́pò ọmọ ẹgbẹ Aṣoju ṣofin fun agbegbe Surulere kinni.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button