Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé iṣé (MOK) Pèsè Okò Ohun Ọ̀gbin Fún Àwọn Àgbẹ̀ Ni Ìpínlẹ̀ Kwara.

0 224

Ilé iṣé Okunlola Kayode Foundation (MOK) to jẹ ilé iṣé alàádáni ní ìjọba ìbílẹ̀ offa ni Ìpínlẹ̀ Kwara ti pèse ọkọ̀ nkán ọ̀gbìn fún àwọn àgbẹ̀ lati ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ètò ọ̀gbìn.

Ilé iṣé náà ló sọ èyí di mímọ̀ nínú ìpàdé pẹlu àwọn ẹgbẹ́ àgbẹ̀ (AFAN) ni offa ìjọba ìbílẹ̀ oyun ní ọjọ́ Sátidé.

Ọ̀gbẹni Saheed Lawal sọ wí pé ilé iṣé náà mọ àwọn àdojúko ti àwọn ni nípa gbingbin nkan ọ̀gbìn ati láti kó oúnjẹ síta fún àwọn ènìyàn, ìdí Nìyín ti ilé iṣé (MOK) fi gbe ìgbésẹ náà.

Bákan náà alága fún ẹgbẹ́ àwọn àgbẹ̀ (AFAN) ọ̀gbẹ́ni Isiaq Adekeye gbóríyìn fún ilé iṣé MOK fún àtìlẹ́yìn wọn.

Ó wà gbàdúrà fún ìtèsíwájú ilé iṣé MOK tó mú irọrun ba àwọn àgbẹ̀

Lára iṣé ti ilé iṣé MOK ṣe láti mú ìrọ̀rùn bá àwọn ará ìlú ní Pín pín oúnjẹ fún àwọn tó kù idẹ fún, ètò ìlera ọfẹ fún àwọn obìnrin àti ọpọ ara ìlú.

Bakan náà ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ fún àwọn ọmọ oniwe méfà ni ìjọba ìbílẹ̀ Oyun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button