Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic (PDP), ti rọ ìjọba Nàìjíríà láti jùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ àti àwọn tó nííṣe láti yanjú ọ̀rọ̀ náà síbi tó rọrùn.
Ẹgbẹ́ náà pe ìpè yìí ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, níbi àpèjọ kan ní ìpínlẹ̀ Bauchi.
Ó ká PDP lára fún bí wọ́n ṣe yọ owó àdínkù epo ilè ní kíákíá láìsí ìfọ̀rọ̀jomi toro ọ̀rọ̀ tó tó.
Asojú Damagum tún sọ pé ìsòkan láàrin àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì àti jákèjádò orílẹ̀-èdè, jẹ ẹgbẹ́ òun lógún.
Ó wá ṣàkíyèsí pé ẹgbẹ́ ti rọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ tí wọ́n dìbò yàn láti ṣe ìjọba tó dára lóri àwọn ará ìlú, ní gbogbo ipele.
Leave a Reply