Take a fresh look at your lifestyle.

Ìyànlóyè: Àgbà òṣèlú APC Kano gbóríyìn fún Gbajabiamila, Akume

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 224

Àgbà òṣèlú APC  Kano kan, Alhaji Haruna Danzago,  gbóríyìn fún ààrẹ Bọla Tinubu fún yíyan Fẹmi Gbajabiamila àti Sẹ́nétọ̀ George Akume gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà fún àwọn òṣíṣẹ́ ààrẹ àti Akọ̀wé fún ìjọba àpapọ̀ (SGF).

Danzago tó ṣe ìgbóríyìn yìí ní ọjọ́ Àìkú ní Kano, ṣápéjúwe yíyàn yìí pé, ó tọ́, tí àwọn méjééjì sì jẹ́ ẹni tí ó tọ́,tí ó yẹ fún àwọn ipò náà.

Ó sọ pé yíyan àwọn arákùnrin méjééjì yìí jẹ́ ìgbésẹ̀ tó tọ́ láti mú àwọn èróńgbà ìjọba Tinubu wá sí ìmúṣe.

Ó ní òun ní ìgboyà pé Gbajabiamila àti Sẹ́nétọ̀  Akume yóò lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrírí wọn nínú ìsiṣẹ́ pẹ̀lú ìjọba,láti mú ìdàgbàsókè òṣèlú tí orílẹ̀-èdè ti ń wá.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button