Gómìnà Agbu Kefas ti Taraba, ti ṣe ìkéde pàjáwìrì lórí ètò ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ àti gíga ní ìpínlẹ̀ náà.
Ó ṣe ìkéde yìí níbi ìbáraẹnisọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn ní ọjọ́ Àbámẹ́ta,ní Jalingo, olú-ìlú,ó sọ pé ìjọba òun yóò mú ẹ̀kọ́ ní dandan, tí yóò sì tún jẹ́ ọ̀fẹ́ fún gbogbo ènìyàn.
Gómìnà sọ pé, ipò ìbàjẹ́ tí ètò ẹ̀kọ́ wà ní ị̀pínlẹ̀ náà kọ òun lómiinú, ó fikun pé ìjọba òun yóò túnbọ̀ ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ìdánilẹ́kọ̀ọ́ nígb̀a gbogbo fún àwọn olùkọ́ni ní ìpínlẹ̀ náà.
Kefas wá pinnu pé òun yóò ṣàgbékalẹ̀ ètò ìwúnilórí fún ìwàlálàáfíà àwọn olùkọ́ni.
Ó wá fi ìpèsè ààbò tótó fún àwọn ènìyàn àti dúkìá dá wọn lójú,tí ó sì sọ pé ààbò jẹ́ oun tó wà lóókan àyà òun.
Leave a Reply