Take a fresh look at your lifestyle.

Owó Epo Pẹntiróòlù Lọ Sókè Lálá Ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Benin

0 120

 

Owó Epo Pẹntiróòlù Lọ Sókè Lálá Ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Benin bí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe gbé ìgbésẹ̀ láti fi òpin sí owó ìrànwọ́ orí epo.

 

Owó epo ti fẹ́rẹ̀ tó ìlópo méjì ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Benin látàrí ìkéde tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ṣe pé àwọn fẹ́ yọwọ́ kúrò pátápátá nínú ìpèsè owó ìrànwọ́ orí epo.

 

Ààrẹ tuntun Nàìjíríà, Bọ́lá Tinúbú nígbà tí wọ́n ń se ìbúra fún sọ pé owó ìrànwọ́ orí epo ti “dópin “. Ìkéde yìí jẹ́ kí ẹ̀rù ba àwọn ènìyàn tí owó Pẹntiróòlù sì fò lọ sókè lálá ní ọjọ́ kejì ìkéde yìí.
Ó di mímọ̀ pé àtúnṣe yóò dé bá gbogbo èyí ní ọ̀ṣẹ̀ tó ń bọ̀.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave A Reply

Your email address will not be published.