Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Tinubu ti yọ owó èlé lórí epo rọ̀bì

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 355

Ààrẹ Nàìjíríà , Bola Ahmed Tinubu sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ níbi ìbúra rẹ̀ sí ipò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ, ní ọjọ́ Ajé pé àsìkò sísan owó èlé lórí epo rọ̀bì ti di ohun ìgbàgbé.

Nígbà tí ó rọ àwọn  ọmọ Nàìjíríà láti wà ní  àlàáfíà àti ìṣọ̀kan, Ààrẹ Tinubu sọ pé “bí ayé básì ń jẹ́ ayé,orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò máa wà.”

“Ìjọba mi yóò bá yín ṣiṣẹ́ pọ̀, kò ní jọba lóri  yín, A ó jọ tún orílẹ̀-èdè yìí ṣe ni.”

Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti gbàgbé òṣèlú ẹléyàmẹ̀yà kí wọ́n sì bá òun fọwọ́ sowọ́pọ̀ fún ìrìnàjò láti sètò orílẹ̀-èdè tuntun àti ìdàgbàsókè ọrọ̀ Ajé.

Aarẹ Tinubu pinnu lati jẹ aarẹ fun gbogbogbòò lai figba kan bọkan ninu, ninu ọrọ rẹ leyin ti Adajọ Kayọde Ariwoọla bura fun tan ní Eagles Square, Abuja.

Fun bii ọgọta ọdun ninu itan, Nàìjíríà ti rarada ipọnju ti ko ba ti fọ agbegbe wa sí wẹwẹ, ṣugbọn aisọretinu ati  agbara bi a ṣe jẹ ẹya oniruuru,jẹ ki a si jọ wa papọ.

Lati tẹsiwaju lori  èròńgbà Nàìjíríà to dara julọ,aarẹ wa rọ awọn ọmọ Nàìjíríà “lati fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹlu rẹ ni sisọ orile-ede Naijiria di orile-ede ti o dara julọ ati ijọba tiwantiwa.”

Aarẹ Tinubu ṣalaye pe,nina oun ja fitafita lati jawe olubori ninu ibo Oṣu Erele 2023 , oun ati alatako oun ti o pinnu pe awọn yoo jọ ṣiṣẹ papọ ni, jọ jẹ ọmọ Naijiria ni.

O ṣàpèjúwe ìbò tí ó gbe wọlé gẹ́gẹ́ bí ohun ti o lágbára ṣùgbọ́n ti oun  borí lódodo, ti o si fi oríire rẹ̀ sọrí orílẹ̀-èdè pẹ̀lú ìpinnu ṣa gbogbo ipa rẹ fun ilọsiwaju orilẹ-ede.

Ọpọlọpọ awọn aarẹ,alakooso,aṣoju ati awọn adari lagbaaye lo wa nijikoo nibi ayẹyẹ ibura naa.

Àwọn ti o tun wa níjòókó ni ààrẹ orílẹ̀-èdè tẹ́lẹ̀ Ajagun fẹ̀yìntì Yakubu Gowon,aarẹ tẹ́lẹ̀ rí Goodluck Jonathan, Adarí ilé-ìgbìmọ̀ Ahmad Lawan, Adarí ilé-ìgbìmọ̀ aṣoju, Femi Gbajabiamila, awọn gomina tẹ́lẹ̀ rí àti lọ́wọ́lọ́wọ́,lọ́balọ́ba àti àwọn adarí ẹ̀sìn,àwọn adarí ìṣòwò àti àwọn aṣojú orílẹ̀-èdè àti àwọn mìíràn.

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button