Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà nípasẹ̀ National Primary Health-Care Development Agency (NPHCDA) tí ṣètò láti ṣé ìfilọ́lẹ̀ Àwùjọ Ìwádìí Innovative-Training and Services Program (CRISP) ni Ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kejilelogun Oṣù Kàrún ùn, Ọdún 2023 ní Banquet Hall ní Abuja.
Olùdarí/Alaṣẹ NPHCDA Dókítà Faisal Shuaib sọ èyí dì mímọ làkókò àpéjọ pẹ̀lú àwọn òníròyìn ní Abuja, Olú-ìlú orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
![]()
O ṣé àfihàn pé Ètò náà yóò kojú àwọn Olutọju Ìbí ibímọ (Skilled Birth Attendants SBA) ní àwọn ilé Ìtọjú Ìlera àkọkọ́ (Primary Healthcare Centres PHC) káàkiri orílẹ̀-èdè.
Dókítà Shuaib ṣàfikún pé ètò náà yóò jẹ́ ìnáwó nípasẹ̀ Ìjọba Orílẹ̀-èdè yìí pẹ̀lú àtìlẹ́yìn láti ọdọ àwọn alabaṣiṣẹpọ ìdàgbàsókè àti àwọn àlàánu láàrín àwọn mìíràn.
Leave a Reply