Take a fresh look at your lifestyle.

Olórin Tó Tún Jẹ́ Òṣèré Ọmọ Nàìjíríà, Ọ̀gbẹ́ni Falz Bẹ̀bẹ̀ Fún Àdúrà Lẹ́yìn Iṣẹ́ Abẹ

0 193

 

Ọmọ Nàìjíríà Olórin tó tún jẹ́ òṣèré, Folarin Falana tí wọ́n ń pè ní Falz ti bẹ̀bẹ̀ fún àdúrà àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí lẹ́yìn Isẹ́ abẹ tó se.

Ó sọ èyí nípasẹ̀ Fídíò tó gbé jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára Instagram wipe ” nǹkan tí òun ń là kọjá báyìí ara òun nílàti bọ̀ sípò pátápátá. E gbàdúrà fún mi.”

Ògbóntàrigi Olórin náà fi ẹsẹ̀ pa ni ìgbà tó n gba bọ́ọ̀lù, wọ́n sì gbàá ní Iyànjú kí ó lọ se iṣẹ́ abẹ kí ara rẹ̀ leè bọ̀ sípò.

Ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé òun lọ se iṣẹ́ abẹ ní ìlú Ọba ní ọjọ́ Kejì oṣù kàrún ọdún yìí. Àwọn Olólùfẹ́ rẹ̀ sì ti ń fi àdúrà ránṣẹ́ sí pé kí Ọlúrun jẹ́ kí ara rẹ̀ tètè yá.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button