Take a fresh look at your lifestyle.

Fídíò Kan, Mílíọ̀nù Kan Dọ́là Ni- TG Omori

0 194

 

Gbajúgbajà olùtẹ orin àti àwọn àwòrán jáde lórí Fídíò nì ThankGod Omori Jesam, tí ìnangi rẹ̀ ń jẹ́ TG Omori tàbí ‘Boy Director,’ ti sọ èròngbà rẹ̀ láti sún oye owó tó ń gbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn lọ sí Dọ́là kan Mílíọ̀nù fún àtẹ̀jáde Fídíò Kan.

 

Ó sọ èyí ní orí ẹ̀rọ ayélujára Twitter rẹ̀ ni ọjọ́ Ọjọ́rú. Ó ní tí òun bá ti se èyí, òun yóò máa tẹ Fídíò ẹyọ méjì péré jáde lọ́dún.

Omori ko síta pé ” Tó bá ti jẹ́ Dọ́là kan soso ni, àwo Fidio méjì péré lọ́dún ni òun máa tẹ̀ jáde fún àwọn ènìyàn”.

Bí àwọn oníròyìn se sọ, Davido jẹ́ kó yé àwọn ènìyàn pé ní oṣù kẹta ọdún, òun sàn Ọgọ́rùn ún Mílíọ̀nù fún TG Omori láti gbé Fidio orin òun tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ ‘Timeless’ jade.

 

TG Omori jẹ̀rí pé òtítọ́ ni òun gba iye owó náà tó gara lọ́wọ́ rẹ̀.
Ó kù díẹ̀ ki àwo orin náà jáde.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button