Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé-ẹjọ́ Malawi paá láṣẹ fún àwọn ilé-ìwé láti fààyè gba irun títakókó

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 257

Ilé ẹjọ́ gíga kan ní Malawi ti pa ilé-iṣẹ́ ìjọba tó ń mójútó ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ lásẹ láti fáàyè gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tírun wọ́n takókó sí ilé ìwé ìjọba ní orílẹ̀-èdè.

Ilé-ẹjọ́ tún paá láṣẹ fún ilé-iṣẹ́ ìjọba náà láti fi àtẹ̀jáde síta ní ọgbọ̀njọ́,oṣù Okùdù,láti kéde gbígbẹ́sẹ̀ kúrò lórí ìfòfin de àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Onírun títa kókọ́, láti lọ sí ilé-ìwé ìjọba.

Ilé-ẹjọ́ tún fagilé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn Onírun títa kókọ́ méjì kan tí wọ́n kò gbà wọlé sí ilé-ẹ̀kọ́ ìjọba ní ọdún 2010 àti 2016 nihtorí pé wọ́n ń dá irun títakókó sí.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button