Wọ́n ti já Blue Aiva, Nana àti Miracle OP dànù nínú Ìdíje Eré.
Lẹ́yìn tí Lawrence àti Ebuka ti kéde wọn ni àwọn alábágbélépọ̀ wọn ti kí wọ́n pé ó dàbọ̀ tí àwọn náà sì fi orí ìtàgé sílẹ̀.
Ebuka bèrè ìrírí wọn lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n lé dànù;
Nana sọ nípa àjọṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Blaqboi àti ẹni tí yóò pàdánù jùlọ nínú ìdíje eré náà.
Miracle OP sọ nípa ànfààní tó ní láti kópa àti ẹ̀kọ́ tó kọ́ níbẹ̀.
Àwọn tí wọ́n já dànù sọ fún àwọn olùwòran pé ó dàbọ̀. Wọ́n sì ti ṣetán láti gbé ìgbé ayé ọ̀tun míràn lẹ́yìn ìdíje eré Big Brother Titans.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply