Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Ènìyàn Ìlú Calabar Gbóríyìn Fún Àjọ Elétò Ìdìbò Fún Ìgbáradì Tí Ó Yarantí

0 212

Àwọn ará ìlú Calabar, ti àgbègbè IBB àti Atimbo ní Ìpínlẹ̀ Cross River ti gbé òsùbà fún Àjọ Elétò Ìdìbò fún ètò tí ó péye àti ìpèsè oun èlò fún ìdìbò lásìkò tí ó yẹ, fún ìdìbò Gómìnà àti asojú ilé ìgbìmọ̀ asòfin ìpínlẹ̀.

Àríwòye wà pé àwọn oun èlò fún ìdìbò tètè dé ibùdó ìdìbò, léyìí tí ó jẹ́ àyípadà rere sí ti ìdìbò gbogbogbòò ti ọjọ́ kẹẹ̀dọ́ọ́gbọ̀n osù kejì.

 

Ìdìbò ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu ní àgbègbè náà tí gbogbo nkan sì ń lọ déédé. Àwọn olùdìbò tú yááyá jáde láti se ojúse wọn, àlàáfíà sì ń jọba ní àgbègbè náà.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button