Ẹgbẹ́ àwọn àgbà ni iwọ òòrun Áfíríkà ti rọ àjọ elẹ́tò ìdìbò, àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò àti àwọn tọrọ kan láti rí wí pé ìdìbò ọjọ́ àbámẹ́ta lọ ni irọwọ ati irọsẹ
Ẹgbẹ́ WAEF sọ èyí ni ìlú Abuja nínú ìwé àtẹjáde ti alaga ẹgbẹ́ náà, àti Ààrẹ orílẹ̀-èdè Ghana tẹ́lẹ̀rí àti Ààrẹ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ ríi Goodluck Jonathan buwọ́lù.
Ẹgbẹ́ náà rọ àwọn tọ́rọ̀ kan lati tẹ lẹ àṣẹ ati òfin ìjọba láti ni ìdìbò ti yóò bù àlàáfíà àti ìrònú ba tilẹ́ tokọ.
Ẹgbẹ́ náà tù rọ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú gbogbo láti wa àlàáfíà láàárín ará wọn, ki wọn sì pa aṣẹ ati ofin ijọba mọ lakoko ìdìbò náà.
WAEF ko yo awon ara ìlú sẹyìn, wọn rọ awọn ọmọ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti ní ìgbàgbọ nínú ìjọba àwarawa àti láti wá àlàáfíà pípé fún ìdàgbàsókè orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Leave a Reply