Take a fresh look at your lifestyle.

A ti sèkìlọ̀ fún àwọn Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Jigawa láti yẹra fún ìwà jàndùkú lásìkò ìdìbò – Ọba Murtala Muhammad Mas’ud.

0 391

Ọ̀ba àwọn Yorùbá ní ìlú Dutse to jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Jigawa ọba Murtala Muhammad Mas’ud,Sarkin Yorùbáwá Dutse emirate ti ni kó tó di ọjọ́ ìbò ni àwọn ti se ìpàdé lọba-lọba láti sèkìlọ̀ fún gbogbo àwọn ọmọ Yorùbá tó ń gbé ni ìpínlẹ̀ Jigawa láti máa lọ́wọ́ nínú ìwà jàǹdùkú àti àwọn ìwà ọ̀daràn míràn lásìkò ètò ìdìbò.

Ọba Murtala Muhammad Mas’ud sọ̀rọ̀ yìí lásìkò ètò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ti àwọn akọ̀ròyìn ilé Akéde Nàíjíríà, Voice of Nigeria, Ademola Adepoju àti Ronke Osunduya sé pẹ̀lú ọba náà ní ààfin rẹ̀ ní ìlú Dutse.

Ọba Murtala Muhammad Mas’ud tún tẹ̀síwájú pé gbogbo àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìbílẹ̀ tó wà ní ìpínlè Jigawa ni àwọn máa ń fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú pàápàá jùlọ nípa ètò ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ náà.

Ọba Murtala Muhammad Mas’ud, tún tẹ̀síwájú láti sọ nípa ètò ìrànlọ́wọ́ ti wọ́n ń ṣe fún àwọn ọmọ Yorùbá tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ Jigawa pàápàá jùlọ nípa ètò ẹ̀kọ́, ètò ìsèlú,yíyanjú aáwọ̀ láàrin ọkọ àti ìyàwó.

Ọba Murtala Muhammad Mas’ud sọ pé ‘Tí èdè àyedè bá wáyé láàárín ọkọ àti ìyàwó, a ó yanjú rẹ̀ ní ìtùbí-ìnùbí,dípò kí wọ́n gbé ara wọn lọ sílé ẹjọ́, ní èyí tí ó leè fa títú ètò ìgbéyàwó wọn ká”.

Ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù kọkànlá, ọdún 2021, ní won fi Emir Dutse fi ọba Murtala Muhammad Mas’ud jẹ ọba Yorùbá ní ìlú Dutse tó jẹ́ olú ìlú Jigawa. tẹ̀síwájú pé gbogbo àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìbílẹ̀ tó wà ní ìpínlè Jigawa ni àwọn máa ń fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú pàápàá jùlọ nípa ètò ìdàgbàsókè ìpínlẹ̀ náà.

Ọba Murtala Muhammad Mas’ud, tún tẹ̀síwájú láti sọ nípa ètò ìrànlọ́wọ́ ti wọ́n ń ṣe fún àwọn ọmọ Yorùbá tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ Jigawa pàápàá jùlọ nípa ètò ẹ̀kọ́, ètò ìsèlú,yíyanjú aáwọ̀ láàrin ọkọ àti ìyàwó.

Ọba Murtala Muhammad Mas’ud sọ pé ‘Tí èdè àyedè bá wáyé láàárín ọkọ àti ìyàwó, a ó yanjú rẹ̀ ní ìtùbí-ìnùbí,dípò kí wọ́n gbé ara wọn lọ sílé ẹjọ́, ní èyí tí ó leè fa títú ètò ìgbéyàwó wọn ká”.

Ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù kọkànlá, ọdún 2021, ní won fi Emir Dutse fi ọba Murtala Muhammad Mas’ud jẹ ọba Yorùbá ní ìlú Dutse tó jẹ́ olú ìlú Jigawa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button