Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Pèsè Àwọn Òun Èlò Amàyédẹ́rùn Fún Àwọn olufaragba Ìṣẹ̀lẹ̀ Ìnà

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 209

Ilé-iṣẹ́ Pájáwìri tí Orílẹ̀-èdè (National Emergency Management Agency NEMA) ní Ọjọ́ Ẹtì pèsè àwọn òun èlò amàyédẹ́rùn fún àwọn tó pàdánù àwọn òun ìní wọ́n sì ìṣẹ̀lẹ̀ iná ní àgbègbè Malamawar-Dangoli, Karange àtí Kwalele ní ìjọba ìbílẹ̀ Kiyawa tí ìpínlẹ̀ Jigawa.

Ìnà tó wáyé ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ karún Oṣu, Ọdún 2023 níbí tí ènìyàn kàn pàdánù ẹ̀mí, tó sí bá òun-ìní run pẹ̀lú àwọn ẹran-ọ̀sin tó tó ọgọrùn mílíọ̀nù náírà N100m.

Olùdarí Àgbà tí Àjọ náà, Mustapha Ahmed sọ èyí làkókò tó pin àwọn òun èlò náà fún àwọn ènìyàn àgbègbè náà tí Ààrẹ Muhammadu Buhari pàṣẹ fún lábẹ́ Mínísítà fún Ọ̀rọ̀ Ọmọnìyàn, Àjálù àtí Ìdàgbàsókè Àwùjọ, látí pèsè àwọn òun èlò iderun náà, èyí tí ẹ̀kà Àjọ náà tó wà ní ìpínlẹ̀ Kano pẹ̀lú ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Àjọ náà tí Ìpínlẹ̀ Jigawa (SEMA).

Olùdarí náà tún kéde mílíọ̀nù kàn náírà tí Ààrẹ tá fí-ìbò-yàn láìpẹ́ yíì, Bola Tinubu fí t’ọrẹ fún àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀lẹ̀ sí.

Tún kà nípa:Àjọ NEMA, NiMet Ńwòye Ọ̀nà Àbáyọ Sí Ìṣẹ̀lẹ̀ Omíyalé Tó N Bọ Wá

Àwọn òun náà ní wọnyí:
* Ẹgbẹ̀wá àpò irẹsi àtí ẹ̀wà òní kilogiramu mẹ̀wàá
* Ẹgbẹ̀rin dín díẹ̀ àpò ọkà
* Ẹgbẹ̀rún àti àábọ̀ aṣọ àwọn ọmọdé
* Ẹgbẹ́ẹdógún ọ̀pá aṣọ àti
* Irínwó aṣọ ìbora

Àwọn mìíràn ní:
* Irínwó aṣọ apẹfọn
* Irínwó matiresi ibùsùn
* Irínwó garawa
* Irínwó abọ́ ìjẹun, ṣíbí àtí ìfé imomi

Gẹ́gẹ́ bó tí sọ, ìjọ̀ba yóò tún pèsè àwọn òun èlò ikọle látí rán wọ́n lọ́wọ́ láti tún ilé wọ́n kọ̀, kí wọ́n lè tèsíwájú nínú ìgbésí ayé wọ́n.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button