Take a fresh look at your lifestyle.

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kwara Ràwọ Ẹ̀bẹ̀ Sí Àwọn Aráàlú Látí Dẹkùn Wiwà Kànga Lọ́nà Ìgbàlódé

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

1 161

Kọmisọna fún ọ̀rọ̀ Omí ìpínlẹ̀ Kwara tí ràwọ ẹ̀bẹ̀ sí àjọ National Association of Hydrogeologists NAH, ẹ̀kà tí Ìpínlẹ̀ náà látí dárapọ̀ pẹ̀lú ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara látí dáàbò bò àyíká àtí dẹkùn wiwà kànga lọ́nà ìgbàlódé láì gbà àṣẹ lọ́wọ́ ìjọba ìpínlẹ̀ náà.

Kọmisọna náà, Dókítà (Ìyàáfín) Risikatullahi Abdulmaliq-Bashir sọ èyí nígbà tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Aláṣẹ tí Ẹgbẹ́ náà ṣé àbẹwò sí ní ọfisi rẹ̀.
Kọmisọna náà sọ pé látí ìgbà tó òún tí bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ́ ní oṣù díẹ̀ sẹyìn ní ẹ̀kà ìjọba náà ní ó tí jẹ́ ẹdun ọkàn fún òún lórí bí àwọn olùgbé Ìpínlẹ̀ náà ṣé wà àwọn kànga wọnyí láì gbà àṣẹ.

Tún kà nípa:Ìbùmu-Bùwẹ̀ Omi Yóò Dúró Fún Ọjọ́ Méjì Ní Ìlú Abuja

Ṣáájú, Alága ẹgbẹ́ náà, Ọ̀gbẹ́ni Lekan Afolami ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aráàlú ló gbára lé lílò àwọn omí wọnyí lórí ètò ọ̀gbìn, ilé iṣẹ́ àtí bẹ́ẹ́bẹ́ lọ̀.
Afolami tẹ̀síwájú pé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ìjọba àtí aráàlú ní yóò dáàbò bò àyíká wà fún ìdàgbàsókè.

Alága náà ṣé ìlérí àtìlẹ́yìn ẹgbẹ́ rẹ̀ sí ìjọ̀ba ìpínlẹ̀ náà atí ní ìdánilójú imurasilẹ rẹ̀ látí kojú ipenija náà.

One response to “Ìjọba Ìpínlẹ̀ Kwara Ràwọ Ẹ̀bẹ̀ Sí Àwọn Aráàlú Látí Dẹkùn Wiwà Kànga Lọ́nà Ìgbàlódé”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button