Ààrẹ Muhammadu Buhari tí fí dá Ìgbákejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Iran lójú pé òún ṣetán láti sọ d’ọtun ìbáṣepọ̀ tó wà lọwọ́ pẹ̀lú Orílẹ̀-èdè Iran
Ààrẹ Buhari sọ èyí lásìkò tí Ìgbákejì Ààrẹ orílẹ̀-èdè Iran, Mohsen Mansouri ṣé àbẹwò sí níbí ìpàdé àjọ àpapọ̀ àgbáyé tó ń wáyé ní Doha, Olú-ìlú orílẹ̀-èdè Qatar.
Ààrẹ tún sọ fún àlejò rẹ̀ nípa ìdìbò tó wáyé láìpẹ́ yìí ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti bí Ààrẹ titun yóò ṣé gbá ìjọba láàárín oṣù mẹta. O fí kún pé òún lérò wípé àjọṣepọ̀ tó lágbára tí òún tí ṣé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì yóò tẹ̀síwájú ní sáà túntún náà.
Tún kà nípa: Nàìjíríà Àtí Íńdíà Ṣe Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Lórí Ìwádìí Ìmọ-jinlẹ̀ Ojú-ọjọ́ Àtí Ìdàgbàsókè
Ìgbákejì Ààrẹ Iran náà sọ pé inú òún dùn láti pàdé pẹ̀lú olórí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ní òye pé àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì ní láti ṣé ìfọ́wọ́sowọlọ̀ pẹ̀lú bí wọ́n ṣé rọ̀rọ́ ní àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n àtí àwọn òun alumọni wọ́n, kí wọ́n sì ṣé ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ní àgbègbè mìíràn bí ìṣẹ́ àgbẹ̀.
[…] […]