Take a fresh look at your lifestyle.

Àwọn Ẹgbẹ́ Kàn Kóró Ojú Sí Ìlànà Títà Àwọn Òun Ìní Ìjọba

Ọlálékan Ọ̀rẹ́núgà

0 82

Ẹgbẹ́ Alátagbà Nàìjíríà (Nigeria Association of Auctioneers NAA), tí bú ẹnu àtẹ́ lú bí ìjọba ṣé ń pàdánù àwọn owó ribiribi nípasẹ̀ bí wọ́n ṣé ń tá àwọn òun ìní tí ilé ẹjọ́ gbà nipasẹ̀ ìwà ajẹbanu lọ́nà àìtọ́ látàrí àìsí òdodo tí àwọn ilé ìṣẹ́ ìjọba ń ṣé.

Ààrẹ ẹgbẹ́ náà, Alhaji Kurra Abubakar sọ èyí làkókò tó ń bá awọn ìròyìn sọ̀rọ̀ ní Abùjá, Olú-ìlú Nàìjíríà bí o ṣé ṣé àkíyèsí pé “Á máa jẹ́ ìbànújẹ fún ẹgbẹ́ náà nigbakugba tí wọ́n bá tá dùkíà tí ilé ẹjọ́ fí òfin dé lọ́nà tí kò bá ìgbà mu.”

Tún kà nípa:Gómìnà Ìpínlẹ̀ Rivers Ṣé Ìfilọ́lẹ̀ Pápákọ̀ Òfurufú Ní Olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Alhaji Abubakar sọ pé “igbesẹ tí àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọ̀ba wọnyí n ṣé máa ṣé ádínkù ìdíyelé oyè owó tó yẹ́ kí ìjọba rí.”

Ààrẹ ẹgbẹ́ náà rọ ìjọ̀ba tó ń bọ̀ látí gbé ìgbìmọ̀ kàn kálẹ̀ tí yóò lọ́ káàkiri orílẹ̀-èdè yíì látí ṣàyẹ̀wò àti òtítọ́ lórí náà wọ́n sì ní ìgbàgbọ́ pé Ààrẹ túntún yóò fí ìgbà ẹgbẹ́ náà láti ṣé iṣẹ́ rẹ̀ bí ìṣẹ́.

Leave A Reply

Your email address will not be published.