Iran àti Saudi Arabia gbà ní ọjọ́ Ẹtì látí tún àwọn ìbáṣepọ̀ wọ́n ṣé lẹ́yìn ọdún méje.
Àdéhùn náà wáyé lẹyìn ọjọ́ mẹ́rin tí ìjíròrò tí kọ́ wáyé ní Ìlú Beijing láàrín àwọn òṣìṣẹ́ ààbò Orílẹ̀-èdè méjèèjì.
Gẹ́gẹ́ bí àlàyé ìbáṣepọ̀ náà tí Orílẹ̀-èdè mẹ́ra fọwọ́ sí Iran, Saudi Arabia àtí China ṣé, Tehran àtí Riyadh gbà láti tún bẹrẹ àwọn ìbáṣepọ̀ wọ́n àtí pé wọ́n yóò ṣí ilé-iṣẹ́ ilẹ́ òkèèrè láàrín oṣù méjì.
“Lára àdéhùn náà ní ibọwọ fún Orílẹ̀-èdè méjèèjì àtí àìsí ayọjuran nínú ètò ìṣèlú àrà wọ́n.”
Tún kà nípa:Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà Gbá Látí Só Ìbáṣepọ̀ Wọ́n Pẹ̀lú Iran Lé dọin-dọin
Ìwé àdéhùn náà ní aṣojú ààbò Iran, Ali Shankhani àtí Oludamọran ààbò Orílẹ̀-èdè Sáúdí Arábíà, Missed bin Mohammed Al-Aiban buwọ́lù ní ọjọ́ Ẹtì, wọ́n sì gbà láti tún mú àdéhùn ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ààbò 2001 ṣiṣẹ́, àtí àwọn àdéhùn mìíràn lórí ìṣòwò, ọ̀rọ̀ àjé àtí Idoko-òwò.
Olori ìlú orílẹ̀-èdè China kàn Wang Yi ṣàpèjúwe àdéhùn náà ní ìṣẹgun fún ìjíròrò àtí àlàáfíà, Ó fí kún pé Ìlú Beijing yóò tẹ̀síwájú látí sá ipá tó múná dóko ní didojukọ àwọn ọran tó ń ṣẹ̀lẹ̀ káàkiri àgbáyé.
[…] Tún kà nípa:Saudi Arabia Àtí Iran Tún Ìbáṣepọ̀ Wọ́n Só dọin-dọin […]