Take a fresh look at your lifestyle.

Iná Màìdúgùri: Ààrẹ Bùhárí gbà wá níyànjú láti máa ṣọ́ra

0 369

Lórí ìjàmbá iná tó ṣẹlẹ̀ ní ọjà gbajúgbajà kan ti wọn pè ní Monday Market ní Maiduguri, Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí ti ní ká ṣọ́ra, nítorí atẹ́gùn àti òòrùn tó ń pọ̀ síi le fa ewu iná nínú igbó, ilé, ilé-iṣẹ́ àti ọjà.

Ààrẹ, tí ó fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn lórí ọsẹ́ tí iná àárọ̀ kùtù ọjọ́ Àìkú òní yìí ṣe, sọ pé orílẹ̀-èdè gbàdúrà, tí ó sì tún bá àwọn olùtajà àti àwọn ẹbí wọn tí wọ́n sọ pé wọn kò rí ǹkankan mú jáde nínú ìjàmbá iná náà kẹ́dùn.

Ààrẹ Bùhárí wá gbóríyìn fún gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Ọ̀jọ̀gbọ́n Bàbágàná Zulum fún bí ó ṣe tètè dìde sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí ó sì pàṣẹ àkójọpọ̀ àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàrin àwọn ilé-iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ àti ti ìpínlẹ̀ láti pèsè ohun ìtura fún àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button