Take a fresh look at your lifestyle.

Ìdìbò 2023 : Àkójọpọ̀ èsì ìbò ń lọ lọ́wọ́ báyìí ní ìpínlẹ̀ Ebonyi

0 327

Kọmíṣọ́nà elétò ìdìbò REC, Ìyáàfin Onyeka Ugochi àti àwọn àgbà elétò ààbò ti gúnlẹ̀ sí Abákáliki, olú-ìlú ìpínlẹ̀ Ebonyi , gúsù iwọ̀ oòrùn Nàìjíríà, níbi tí àkójọ ìbò ti ń lọ lọ́wọ́ láti mú kí ètò fífi èsì ránsẹ́ wáyé ní kíákíá.

Èyí wáyé látàrí ìfàsẹ́yìn ìkójọ àti fífi èsì ìbò ránṣẹ́ sí olú ilé-iṣẹ́ ìgbìmọ̀ olómìnira tó ń ṣètò ìbò INEC,ní Abákáliki ,olú ìlú náà.

REC sọ pé, títí di agogo mọ́kànlá òwúrọ̀, ọjọ́ Àìkú,èsì ìbò ẹ́ẹ́rìnlá-dín-ní-ọ̀tà-lé-lẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ́ẹ́ẹdógún ibùdó ìdìbò láti ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́tàlá kò tíì dé ọ̀dọ̀ òun, REC tún sọ pé àwọn ọ̀ga àgbà elétò ààbò ti tẹ̀ síwájú ní àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tó kù fún àkójọ àti èsì ìbò.

A ó rántí pé, àjọ INEC fagilé ibùdó ìdìbò mẹ́rin kan tí ó kọ́kọ́ dá sílẹ̀, nítorí pé kò ní sí ìbò kan dábí alárà níbẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button