Take a fresh look at your lifestyle.

Èsì Ìbò ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́wàá wọlé fún Àjọ INEC nínú ogún

0 336

Àjọ elétò ìdìbò lórílẹ̀-èdè Nàíjíríà (INEC), ní ìpínlẹ̀ Ògùn , ẹkùn gúsù iwọ̀ oòrùn Nàìjíríà, ti fìdíẹ̀ múlẹ̀ pé òun ti gba èsì ìbò ààrẹ wọlé ní ìjọba ìbílẹ̀ mẹ́wàá.

Kọmíṣọ́nà ètò ìdìbò (REC), ti ìpínlẹ̀ yìí, Níyì Ìjàlàyè ló sọ èyí di mímọ̀ ní ọjọ́ Àìkú, nígbà tí ó ń ṣí ibùdó àkójọpọ̀ ìbò ní ìpínlẹ̀ náà.

Ó tún kéde pé ọ̀gá àgbà ilé-ìwé gíga fáfítì ti Ìbàdàn, Ọ̀jọ̀gbọ́n Káyọ̀dé Oyèbọ̀dé Adébọ̀wálé ni yóò ṣe agbátẹrù àkójọpọ̀ èsì ìbò ní ìlú náà.

Ìjálayè ka àwọn ìjọba ìbílẹ̀ tí èsì wọ́n ti wà nílẹ̀: Àríwá Rẹ́mo, Ikenne, iwọ̀ oòrùn Ègbádò àti Ewékorò.

Àwọn tí ó kù ni: Àríwá Abẹ́òkúta , Àríwá Ìjẹ̀bú , iwọ̀ oòrùn Àríwá Ìjẹ̀bú , Ìmẹ̀kọ Afon, Ọdédá àti ìjọba ìbílẹ̀ Àríwá Ẹ̀gbádò.

Ní àsìkò tí ìròyìn yìí ń wọlé, Ọ̀jọ̀gbọ́n fún ìpínlẹ̀ náà gba àwọn èsì náà wọlé.

Àlàyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ ńbọ̀ láìpẹ́…

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button