Take a fresh look at your lifestyle.

Gómìnà Seyi Makinde Àti Asofin Teslim Folarin náà Ti Dìbò Ààrẹ Àti Ilé Ìgbìmò Aṣojú-Ṣofin, ọdún 2023

0 291

Bí ètò idibo Ààrẹ àti Ilé Ìgbìmò Aṣojú-Ṣòfin ṣe n lọ lọwọ jake-jado Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ Seyi Makinde náà ti lọ dibo tirẹ.

Gómìnà Seyi Makinde ẹni tí o lọ ṣe ojúṣe rẹ ni Wọọdu Kọkànlá ni ibùdó ìdìbò 002, ni Ìjọba Ibilẹ Ìlà Oòrùn Àríwá Ìbàdàn ló gbe osuba kare fún àwọn òṣìṣẹ́ àjọ eleto ìdìbò ní Ìpínlè Ọ̀yọ́ fún bí ètò ìdìbò náà ṣe n lọ ní irọwọ-rọsẹ.

Makinde àti aya rẹ Abileko Tamunominini Makinde lo wà lati ṣe ojúṣe wọn ni déédé agogo Mẹwa kọja isẹju marundinlogun owurọ, tí o sì rọ gbogbo oludibo láti dibo fún ẹni tí o bá wù wọn.

Bákan náà ni ẹni tíì ṣe oludije du ipò gómìnà labẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú APC, Aṣòfin Teslim Folarin náà ló ṣe ojúṣe rẹ gẹgẹ bíi oludibo ní Wọọdu 5, ibùdó ìdìbò 002, ni Ìjọba Ìbílè Ònà-Ara, ni déédé agogo Mọkanla kọjá Ogún iṣẹju.

Pẹlu ipenija tí o jẹyọ nípa bí ẹrọ tó n ṣe ayẹwo ati idanimọ oludibo, BVAS ko ṣe ṣiṣe bi o ti yẹ, àwọn oṣiṣẹ àjọ eleto ìdìbò fi oludibo lọkàn balẹ ti wọn sì n fi ẹrọ náà ya aworan ojú àwọn oludibo ti ètò ìdìbò sí lọ bo ti tọ àti bí o ti yẹ.

Gẹgẹ bí ọkan lára oludibo ni Wọọdu 9, ibùdó ìdìbò 16, Sola Adeyemo ṣe ṣàlàyé ìrírí rẹ, “Ẹrọ BVAS kò ṣiṣẹ́, kò mú àwòrán ìka ọwọ́ jáde, nígbà tí ko ṣiṣẹ, wọ́n ní láti yà fọto ojú wá,…. ẹrọ BVAS náà ko ṣiṣẹ.

Ọgbẹni Adeyemo tún fi kún àlàyé rẹ̀ nígbà tí o n sọ iriri rẹ̀ wí pé ọpọlọpọ oludibo lo tètè dé sí ibùdó ìdìbò ṣugbọn tí àwọn míràn kò rí orúkọ wọn lára orúkọ àwọn oludibo to wa ní ibùdó ìdìbò náà.

O wá gba àjọ eleto ìdìbò, INEC lati wá àtúnṣe sí ẹrọ BVAS ti ko ṣiṣẹ bo ti yẹ kó ṣiṣẹ kí irufẹ iṣẹlẹ bayii má bà wáyé lójó ìdìbò Gómìnà àti ọmọ ilé ìgbìmò Aṣofin to n bọ ní ọjọ kọkànlá oṣù kẹta ọdún yìí.

 

Abiola Olowe
Ìbàdàn

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button