Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹ jẹ́ kí èsì ìbò jẹ́ àtẹ́wọ́gbà: Aisha Buhari

0 299

Arábìnrin Àkọ́kọ́ ní Orílẹ̀ Èdè Nàìjíríà, Aisha Buhari rọ àwọn obìnrin àti ọ̀dọ́ láti pa òfin ìdìbò mọ́ àtipé kí wọ́n faramọ́ ẹnikẹ́ni tí àjọ elétò ìdìbò bá kéde gẹ́gẹ́ bíi ẹni tí ó jáwé olúborí.

 

Ó sọ èyí di mímọ̀ ní kété tí ó dìbò tán ní ìbùsọ̀ ìdìbò rẹ̀ ní ìlú Daura, Ìpínlẹ̀ Katsina. Ó ní ìrètí wà pé ìjọba tí ó ń bọ̀ lọ́nà yóò tẹ̀síwájú pẹ̀lú iṣẹ́ rere tí Ààrẹ Buhari ti ṣe.

 

Arábìnrin Buhari wá fi àrídájú hàn pé olùdíje sí ipò ààrẹ lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú APC ni yóò jáwé olúborí àti gbogbo àwọn olùdíje tókù lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ náà.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button