Take a fresh look at your lifestyle.

Fúnkẹ́ Akíndélé Sọ̀rọ̀ Látàrí Ikú Ìyá Rẹ

0 267

 

Oǹdíje igbákejì Gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) ní Ìpínlẹ̀ Èkó, Funke Akindele ti fọhùn látàrí ikú ìyá rẹ̀ Dokita, RB Adebanjo-Akindele.

Nínú àtẹ̀jáde Instagramu rẹ̀, Funkẹ se ìrántí ìyá rẹ̀ ní ìgbàtí ó máa ń sọ fún láti tẹra mọ isẹ́, kò jẹ́ olùfokàn sìn, kó má se ní ìwà ìmọ tara ẹni nìkan.

Ó jẹ́ kó di mímọ̀ pé, ìyá òun tó ti lọ, se bẹbẹ nínú ayé àwọn ọmọ òun àti gbogbo àwọn tó súnmọ́ ìyá òun kọ́lọ́jọ́ tó dé.

Ẹ̀gbọ́n Funkẹ, Olubunmi Akindele, sọ ìpapòdà ìyá won ní orí ẹ̀rọ ayélujára Instagramu ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, pé ìyá wọn papòdà ní ọjọ́ keje oṣù Kejì ọdún 2023.

Olùdásílẹ̀ eré “Jenifa Diary”, fi kún un pé ìpapòdà ìyá òun dun òun sùgbọ́n òun le yangàn nínú ogún rere tó fi sílẹ̀, òun yóò sì máa tẹ̀ síwájú nínú rẹ̀ láti lè má fi bu ọlá fún ùn.

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button