Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Kwara United Yan Kabir Dogo Gẹ́gẹ́ Bí Akọ́ni-mọ̀ọ́gbá

1 185

 

Àjọ Nigeria Professional Football League (NPFL) ti ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Kwara United FC ti Kéde ìyànsípò akọ́ni-mọ̀ọ́gbá tẹ́lẹ̀ ìkọ Wikki Tourists FC, Kabir Dogo, sí ipò akọ́ni-mọ̀ọ́gbá tuntun fún ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù wọn tó wáyé ní ìlú Ìlọrin, olú ìlú Ìpínlẹ̀ Kwara.

Dogo ló rọ́pò Abdulazeez Mohammed tó kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀. Ìyànsípò rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ní wàrànsesà.

Alága ẹgbẹ́, Kumbi Titiloye sọ pé “ó se pàtàkì láti tètè yan ẹlòmíràn kì àlàfo má bà sí sílẹ̀ ní àkókò tó se pàtàkì yìí”.

Ní abẹ́ ìdarí ọ̀gbẹ́ni Mohammed, Kwara United borí ìdíje ní ìgbà kan, ó pàdánù ìdíje mẹ́rin, ó ta ọ̀mìn ní ìgbà méjì nínú gbogbo ìdíje méje tí wọ́n gbá lápapọ̀.

“A ti tẹ́wọ́ gba lẹ́tà ìfiṣẹ́ sílẹ̀ rẹ̀ bí òun náà ti gbà pé òun ni òun se òkùnfà ìfìdírẹmi ìkọ náà”.
“A kò le tẹ̀síwájú nínú èyí lẹ́yìn gbogbo akitiyan àti àtìlẹ́yìn ìjọba, alábójútó àti àwọn èèkàn gbogbo”.
Alága ẹgbẹ́ Aagbábọ́ölù Titiloye sọ èyí.

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

One response to “Ẹgbẹ́ Agbábọ́ọ̀lù Kwara United Yan Kabir Dogo Gẹ́gẹ́ Bí Akọ́ni-mọ̀ọ́gbá”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button