Beyonce ti wá di Oǹkọrin tí ó ti gba àmì ẹ̀yẹ jùlọ nínú ìtàn àmì ẹ̀yẹ gbígbà ti GRAMMY.
Ní ọjọ́ Àìkú, ní ìgbà tí wọ́n ń se ayẹyẹ ẹlẹ́karùn dín láàdọ̀rin irú rẹ̀ ọlọ́dọọdún, ó gba ife ẹ̀yẹ Èkejìlélọ́gbọ̀n gẹ́gẹ́ bí ẹni tó se dáadáa jù nínú Dance/Electronic Music Album nínú orin rẹ̀ tó pè ní ” Renaissance”.
Ìjáwé olúborí Beyonce ní ti ọ̀kàndínlọ́gbọ̀n, ọgbọ̀n àti ọ̀kànlélọ́gbọ̀n jẹ́ àseyege rẹ̀ nínú ti Dance/Electronic Recording, Best Traditional R&B Performance àti orin R&B to dára jù.
Fún àṣeyọrí àti àmì ẹ̀yẹ tó gbà yí, ó lọ sí ojú òpó ayélujára Instagramu ó kí àwon olólùfẹ́ rẹ̀, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún àseyege rẹ̀.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
Leave a Reply