Take a fresh look at your lifestyle.

Àjọ FCTA Gbá Ogún Ènìyàn Tó Ń Fi Ẹ̀rọ POS Ṣiṣẹ́ Níbití Kò Tọ́ Mú

0 228

 

Àjọ Federal Capital Territory Administration (FCTA) ti gbá ogún èniyàn tó ń fi ẹ̀rọ, Point of Sale (POS) ṣiṣẹ́ níbi tí kò tọ́ mú ní ọjọ́ ẹtì ní Abùjá.
Wọ́n gbá àwọn ènìyàn mú lẹ̀bá ọ̀nà, àti gbogbo ibi tí ìjọba sọ wí pé kí wọ́n má ti ṣiṣẹ́.

Ó di mímọ̀ pé, àwọn kan tí àwọn ènìyàn kò mọ̀ ń rìn káàkiri ní Abùjá tí wọn ń díbọ́n bí ẹni pé òṣìṣẹ́ tó ń fi POS ṣiṣẹ́ ni wọ́n.

Olùgbani nímọ̀ràn pàtàkì fún Mínísítà to sojú fún ìlú Abùjá lórí àbújútó, ìbẹ̀wò àti fífi òfin lọ́lẹ̀,Ikharo Attah bá àwọn arúfin náà sọ̀rọ̀ ní agbègbè Abùjá Environmental Protection Board (AEPB) Area 3. Ó so wí pé Mínísítà kò ni lọ́kàn rárá láti dá àwọn tó n fi POS ṣiṣẹ dúró, sùgbón okùn ààbò ni wọ́n fẹ́ so kó le dáadáa.

Attah so wí pé àwọn arúfin náà ní wọ́n o gbé lọ sí ilé ẹjọ́ alágbéká látàrí tí tàpá sí òfin ìjọba nípa ṣíṣe òkòwò wọn ní àyíká tí ìjọba kò fọwọ́ sí.

Ẹni kan tí wọ́n gbá mú, ògbéni Solomon Wari, òṣìṣẹ́ ìjọba sọ pé wọ́n mú òun ní iwájú àyíká ibùgbé ní Wuse zone 6 tí òun ti n ṣiṣẹ́ náà, ó sì ṣèlérí pé òun kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button