Mínísítà tí ó wà fún ètò òṣìṣẹ́ àti ìgbaniṣíṣẹ́, Chris Ngige ti sàgbékalẹ̀ ìlànà tí yóò tán ìsòro àìríṣẹ́ se ní ilẹ̀ Nàìjíríà.
Mínísítà síṣọ lójú ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹka àjọ òṣìṣẹ́ kan ní ìlú Abuja. Ó sàfikún pé ìjọba yóò bẹ̀rẹ̀ ìsàmúlò ìlànà náà láìpẹ́, lójúnà àti tán ìsòro iṣẹ́ àtipé yóò fún olúkúlùkù ní ànfààní láti mọ irúfẹ́ iṣẹ́ tí ó wà pẹ̀lú ọ̀nà àti wá iṣẹ́ náà.
Ngige sàfijọ ìgbésẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi irú èyí tí orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà se láti tán ìsòro àìríṣẹ́ se tí ìrètí sì wà pé tí ètò náà bá bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu, ìsòro àìríṣẹ́ yóò di àfìsẹ́yìn tí egúngún ń fi aṣọ.
Leave a Reply