Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà Ti Gbáradì Fún Ìdásílẹ̀ Ilé-Ìwòsàn Àrùn Jẹjẹrẹ

0 146

Ọ̀gá àgbà Ilé Ìwòsàn ( African Medical Centre) Brain Deaver sọ pé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti parí ètò láti dá Ilé ìwòsàn àrùn jẹjẹrẹ sílẹ̀.

 

Deaver se ìfiléde ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ó se àbẹ̀wò sí alákòsóo àjọ tí ó ń mójú tó ọ̀rọ̀ ọmọ Nàìjíríà ní òkè òkun, Abikẹ Dabiri Erewa.

 

Deaver tún sàlàyé pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ilé-Ìwòsàn orílẹ̀ èdè wa ni ó jẹ́ gbogbo nìṣe, eléyìí sọ dídásílẹ̀ Ilé ìtọ́jú àìsàn Jẹjẹrẹ di pàtàkì ní àwùjọ wa.

 

Alákòsóo náà parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìdásílẹ̀ irúfẹ́ Ilé- Ìwòsàn bẹ́ẹ̀ yóò pèsè iṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onímọ̀ ètò ìlera àtipé yóò mú kí àwọn tí ó ti lọ sí òkè òkun fún irúfẹ́ iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ padà sílé.

Leave A Reply

Your email address will not be published.