Take a fresh look at your lifestyle.

Ààrẹ Buhari Tún Yan Adeyeye Gẹ́gẹ́ Bí Olùdarí Àgbà NAFDAC

0 309

Ààrẹ Muhammadu Buhari tí tún yàn Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye gẹ́gẹ́ bí Olùdarí àgbà fún ilé iṣẹ́ alabojuto Oúnjẹ àtí Oògùn National Agency for Food and Drug Administration and Control (NAFDAC), fún ìgba Kejì fún ọdún Márún ùn mìíràn.

Akọ̀wé sí ìjọba tí Orílẹ̀-èdè yìí, Ọ̀gbẹ́ni Boss Mustapha ló sọ èyí dì mímọ tí àkókò rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ látí ọjọ́ kíní Oṣù Kejìlá ọdún 2022.

Iyán ní sí ipò Olùdarí àgbà NAFDAC náà wáyé látàrí iṣẹ́ ribiribi àti àṣeyọrí tí o ṣé gẹ́gẹ́ bí adari pàápàá jùlọ ìdàgbàsókè ní Àjọ Àgbáyé tí Ìlera (WHO) sí ìpele kẹta

Ọdún 2017 ní wọ́n yàn an sípò gẹ́gẹ́ bí Adari, àkókò ìṣàkóso rẹ̀ sí pé ní ọjọ́ Kejì, Oṣù kọkànlá, ọdún 2022.

Ní kété tí ìṣàkóso náà tán ní Dókítà Monica Eimunjeze gbà ipo gẹ́gẹ́ bí fìdíhẹ̀ ni ọjọ́ Kejìlá oṣù kọkànlá, ọdún 2022.

Ọjọgbọn Adeyeye tí gbà iṣẹ́ ní Ọjọ́ Ẹtì, ọgbọ̀n ọjọ́ oṣù Kejìlá tí àwọn òṣìṣẹ́ ní Ilé-iṣẹ́ náà ní olu-ilu Abùjá, Nàìjíríà.

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button