Ilé-iṣẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó ń rísí ètò Ìdàgbàsókè ilẹ̀ ọ̀gbìn (NALDA),ti ṣàlàyé pé, kò ní sí àìtó oúnjẹ ní orílẹ̀-èdè, tí ó sì tún ń fi dá àwọn ọmọ Nàìjíríà lójú pé eebi kò ní pa wọ́n ní ọdún 2023.
Ọmọ ọba Ikonne,Akọ̀wé àgbà/Ọ̀gá àgbà ilé-iṣẹ́ NALDA, ni ó sọ èyí di mímọ̀ lásìkò tí ààrẹ Mùhámmádù Bùhárì ń ṣísọ lójú àṣeyọrí pàtàkii NALDA, fún àwọn akọ̀ròyìn, láàrin ọdún méjì ní Àbújá .
Ó tún wá sọ síwájú pé, kò sí ìbẹ̀rù kankan lórí ohun tí àwọn ènìyàn àti àwọn ẹgbẹ́ kan ti ní lọ́kàn àti àsọtẹ́lẹ̀ pé ìyàn yóò mú ní Nàìjíríà lọ́dún 2023.
Bákannáà, ó sọ pé lábẹ́ àkóso àkójọpọ̀ NALDA jákèjádò orílẹ̀-èdè,ìkórè oúnjẹ tó tó ti wà nílẹ̀ tí ó sì tún ń lọ lọ́wọ́.
Leave a Reply