Take a fresh look at your lifestyle.

Ilé-ìgbìmọ̀ Aṣojú Ṣòfin Pé Àwọn Olórí Ààbò Lórí Bí Wọ́n Kò Ṣé Ń Dunadura Pẹlú Ilé Iṣẹ̀ DICON

0 425

Ìgbìmọ̀ Aṣojú Ṣòfin lórí Ààbò tí pé gbogbo àwọn olórí ilé-iṣẹ́ ààbò nì orílẹ̀-èdè yìí nítorí bí wọn ṣé kọ̀ láti máa ra òhun ìjà àti ọdọ Defence Industry Corporation of Nigeria (DICON).

Alága ìgbìmọ̀ náà Hon Babajimi Benson, kéde ìpè náà nígbà tí Olùdarí àjọ DICON, Major General Hassan Tafida, farahàn níwájú ìgbìmọ̀ rẹ̀ lórí ìṣúná 2023 ti ilé-iṣẹ́ náà.

Hon. Benson sọ pé ọ ṣé pàtàkì fún àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò ti orílẹ-èdè yìí láti kọkọ wá àwọn òun ìjà ní orílẹ̀-èdè yìí kì wọ́n tó lọ sí òkè òkun. Àwọn aṣòfin yóò fi ipá mú gbogbo àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò láti rà awọn òun ìjà lọwọ DICON. Bẹ́ẹ̀ náà ló kàn àwọn ọmọ ogún ofurufu àti ojú omi. Lórí ìdí èyí, owó wà yóò gberasọ ni ọjà paṣipaarọ, yóò mú ìlọsíwájú bá ètò ẹ̀kọ́ imọ-ẹrọ àti ipèsè iṣẹ fún awọn ọdọ wa.” Hon. Benson sọ.

Nínú ọrọ rẹ, Olùdarí Gbogbo-gbòò tí àjọ náà, Major General Hassan Tafida, fí ẹsùn kàn àwọn ilé-iṣẹ́ ààbò tí kò ṣé àtìlẹ́yìn DICON nípa ríra àwọn òhun ìjà ni òkèèrè nítori pé kò sí òfin tó dé wọ́n ní.

O sọ pé àwọn ènìyàn láti ilé-iṣẹ́ aladaani n ṣé àjọṣepọ̀ pẹlú DICON nípasẹ̀ kíkọ àwọn ilé-iṣẹ́ l’ọpọ, ṣiṣẹ àwọn Carriers Armored Personnel àti ìṣe l’ọpọ àwọn òhun ìjà.

O fi kún pé gbogbo òhun tí a nilo láti ní ìrànlọ́wọ́ ilé iṣẹ́ imọ-ẹrọ ti orilẹ-ede yìí, fún òmìnira ará rẹ̀.

Lekan Orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button