Take a fresh look at your lifestyle.

Àdéhùn Láàrín Russia Àti Àjọ Àgbáyé (UN) Lórí Ọjà Òkèèrè

0 323

Russia tí fí ìwé ẹdun ọkàn nípa ìwé ìṣẹ́ àdéhùn ọjà òkèèrè tí Black Sea Grain sí Àjọ Àgbáyé (United Nations).

Gennady Gatilov, aṣojú Russia sí United Nations, sọ pé “Ta bá ríi pé kò sí àtúnṣe sí ìwé àdéhùn náà, lórí ètò àwọn ọkà ati ajilẹ tí Russia sí ilẹ̀ òkèèrè, ojú míràn la o fí rí.”

O sọ pé: “O ṣeéṣe kí àwọn má fọwọ́ sí ìtèsíwájú ìwé àdéhùn náà. A kó lòdì sí ètò kì kó ọkà àti ajilẹ lọ́ sílè òkèèrè ṣùgbọ́n àdéhùn yìí gbọ́dọ̀ jẹ́ dọgbadọgba, tòótọ́ àti òdodo fún olukuluku.”

Agbẹnusọ UN Stephane Dujarric sọ pé: “A tí ń ṣé ìgbìyànjú láti bá àwọn òṣìṣẹ́ Ìjọba Russia pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba láti European Union, United Kingdom ati United States láti yọ àwọn idiwọ tó ń kojú ijoba Russia lori àdéhùn náà.”

Adehun náà ní Àjọ Àgbáyé àti Turkey dálẹ̀ rẹ̀ ní Oṣù Keje, bó ṣe fayé gbà Ukraine láti bẹrẹ sí gbé ọkà lọ sílẹ̀ òkèèrè láti èbúté-kọ ojú omi Òkun Dúdú tó tí wà lábẹ́ ìjọba orílẹ̀-èdè Russia lẹyìn ikọlù.

Àdéhùn náà ṣé ìrànlọ́wọ́ oúnjẹ lọpọ yanturu làgbáyé. Russia ati Ukraine jẹ olùtajà ọkà tó tóbi jùlọ ní àgbáyé bẹ́ẹ̀ Russia tun jẹ́ olùtajà ajilẹ tó jù lágbàyé.

Ìlú Moscow tí sọ nínú ọrọ rẹ̀ nípa ètò náà, to sí kóró ojú lórí títà ajilẹ àti àwọn oúnjẹ rẹ̀.

Lekan orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button