Take a fresh look at your lifestyle.

Nàìjíríà Ṣé Ayẹyẹ Òmìnìra Ọdún Kejìlélọ́gọ́ta

0 305

Orílẹ-èdè Nàìjíríà ṣé ayẹyẹ ìrántí Òmìnìra ọdún Kejìlélọ́gọ́ta ní ọjọ Àbámẹ́ta ni gbangan nlá olókìkí nì Eagle Square, tó wà láàárín gbùngbùn Olú-ìlú orílẹ-èdè, Abùjá.

Ààrẹ Muhammadu Buhari ní àlejò pàtàkì ayẹyẹ náà tó sí tún ṣé àbẹwò sí àwọn ọmọ Ogún to dúró déédé.

Ààrẹ dé ibí ipagọ náà ní déédé ago mẹsan owurọ (09:00 GMT) bí àwọn ẹṣọ́ ṣé fi alupupu ati ẹṣin Ààrẹ dára tó sí mú orí ẹní wù

Lẹyìn tí wọ́n kọ̀ Orin ìyìn orílẹ-èdè (National Anthem), Ajagun Lt. Col. Yusuf Hassan pé Ààrẹ láti ṣàyẹ̀wò àwọn ọmọ Ogún èyí tí Brig. Gen. Mohammed Usman tó jẹ́ olùṣọ àwọn ọmọ Ogún rìn pẹlú Ààrẹ. Àwọn ẹṣọ́ ologun, ẹgbẹ afárá jẹ́ ológun àti àwọn ẹgbẹ́ National Youth Service Corps ni wọn to lẹsẹsẹ.

Èyí ní atẹle bí àwọn ológun ojú òfurufú ṣé ń fò sínú ipagọ náà láti inú ọkọ òfurufú pẹlú àwọn ajá wọ́n to ń ṣàfihàn bí wọ́n ṣé lé gbà ènìyàn kúrò nínú ìgbèkùn.

Bí ayẹyẹ náà tí ń lọ sí ìparí, ìbọn yín yín soke oni ogun-le-kan (21) àwọn tí a mọ̀ sí (Firing of Artillery volleys ló wáyé. Leyin eyi ni Ààrẹ buwọ́lù ìwé ìrántí aṣeyẹ Òmìnira fún ìgbà ìkẹyìn nínú ìṣàkóso rẹ̀.

Lẹyìn èyí ní àwọn omo ológun ṣé ajọyọ pẹlú ariwo ayọ̀ mẹta fún Ààrẹ Buhari tí wọ́n sì kọ orin ìyìn orílẹ̀-èdè láti fí adagba ètò náà rọ.

Àwọn ènìyàn pàtàkì tó tún wà ní ipagọ Eagle Square yìí ní Ààrẹ Nàìjíríà nìgbàkànrí, Goodluck Jonathan, àti Igbákejì Ààrẹ Yemi Osinbajo, Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, Ahmed Lawan, Agbẹnusọ ile igbimo Aṣojú-ṣofin àgbà, Femi Gbajabiamila, Adájọ àgbà ilẹ Nàìjíríà, Onídàájọ Olukayode Ariwoola. Olori Òṣìṣẹ́ Ààbò Gbogbogbò Lucky Irabor, Ọgá àgbà awọn ọlọ́pàá àtí bẹẹbẹ lọ.

Lekan orenuga

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button