Kabul: Aa! Ìkọlù Ìpànìyàn Àti Igbẹ̀mi Ara Ẹni Ní Gbọ̀ngàn Ìdánwò Dá Ọ̀kàndínlógún Ẹ̀mí Ènìyàn Légbodò
Ìkọlù Ìpànìyàn àti ìgbẹ̀mí ara ẹni ní gbọ̀ngàn ìdánwò ti dá ọ̀kàndínlógún èmi ènìyàn légbodò tí ọ̀kè àìmọye ènìyàn sì farapa ní Kabul Olú ìlú Afghanístàn.
Agbẹnusọ Ọlọ́pàá Kabul, Khalid Zadran sọ wípé ìṣẹ̀lẹ̀ náà sẹlẹ̀ ní gbọ̀ngàn ilé ẹ̀kọ́ níbi tí ìdánwò ìgbaniwọlé ti ń wáyé.
Ògbéni Zadran sọ wípé ènìyàn mọ́kàndínlógún ló j’Ọlọ́run nípè àti pé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n ènìyàn ló farapa.
Ó fi kun pé ilé ìwé máa ń sábà kógbâ wọlé ní ọjọ ọjó ẹtì.
Wọ́n sọ wípé o ṣeéṣe kí iye ènìyàn tó kú sì lọ sókè. Ènìyàn mẹ́tàlélọ́gbọ̀n ti di olóògbé ti àwọn obìnrin sí wà lára wọn, gẹ́gẹ́ bí ìròyìn láti ọ̀dọ̀ àwọn Taliban se sọ.
Láti ìgbà tí àwọn Taliban ti gba ìjọba nínú osù kẹ́jọ ọdún 2021 ni wọ́n ti sọ pé àwọn ń dábòbò orílè èdè. Sùgbón ní nkàn bíi oṣù díẹ sí àkókò yìí ni ìró kẹ̀kẹ̀ ìbọn àti àdó olóró ti n ṣẹlẹ̀ ní àárín ilú àti àwọn Mọ́sálásí káàkiri.
Àwọn ọ̀dọ́ omo ilé ìwé tí wọ́n dín ní ogún odun wà lára àwọn ènìyàn mẹ́rìnlélógún tí wọ́n pa nínú ìkọ̀lù ọdún 2020 ní gbọ̀ngàn ilé ẹ̀kọ́ ní ìwọ̀ oòrùn Kabul tí àwọn Mùsùlùmí orílè èdè náà sọpé àwọn lówà ní ìdí rẹ̀.
Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san
| ReplyForward |
Leave a Reply