Take a fresh look at your lifestyle.

Kòkó: Ìròyìn Ayọ̀! Ẹgbẹ̀rún Lọ́nà Àádọ̀rin-dín-méjì Àgbẹ̀ Yóò Jàǹfààní Ìrànwọ́ Amẹ́ríkà

0 533

Ó kéré tán, àgbẹ̀ ní orílè-èdè Nàìjíríà ní ìpínlè Abia, Cross River, Ekiti, Akwa Ibom, Ondo ati Osun ni yóò jẹ ànfààní Ìrànwọ́ orílè-èdè Amẹ́ríkà ní ẹ̀ka ètò ìmúgbóòrò kòkó.

Ẹ̀ka  orílè-èdè Amerika tó wà fún Ètò Ogbin fún itẹsiwaju ló sọ èyí nínú àkọsílẹ tó tẹ̀lé ètò àjosepọ̀ láàrin Lutheran World Relief lati ro ìpèsè kòkó ní agbára ní orílè-èdè Nàìjíríà.

Àkọsílẹ náà fihan pe, eto ti iye rẹ̀ to Mílíọ̀nù méjìlélógún dọ́là
ni wọ́n yóò fi sójú ìṣe fún ọdún márùn ùn tó ń bọ̀ ní ṣíṣẹ̀ n tẹ̀lé

Nígbàtí ó ń sòrò, kanselọ̀ fún ètò ọ̀gbìn ti U.S. Mission fun orílè-èdè Naijiria, Dokita, Gerald Smith, je ko di mímọ pé ètò náà yóò dojúkọ àwọn àgbẹ̀ aládàá kékeré sùgbón ní agbègbè àti ilẹ̀ tí ó dára láti jẹ́ ki ìpèsè kòkó gbòòrò síi, kí ilẹ̀ túnbọ̀ lọ́ràá síí.

 

 

Tèmítọ́pẹ́ Òbísẹ̀san

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button