Ọ̀gá àgbà àjọ tí ó ń mójú tó ètò ìdánwò ìgbaniwọlé sí ilé ẹ̀kọ́ gíga, ọ̀jọ̀gbọ́n Ishaq oloyede ti pa àrọwà sí ìjọba láti máa pèsè owó fún àjọ náà fún síse àkóso àwọn ètò rẹ̀. Ó rọ ìjọba láti máa se dásí ọ̀rọ̀ ìnáwó àjọ náà mọ́.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Oloyede fi ọ̀rọ̀ náà léde ní ilé ìgbìmọ̀ asòfin, nígbà tí ó fi ara hàn níwájú àwọn ìgbìmọ̀ tì ò ǹ mójú tó ètò ìsúná owó. Ó pè fún sísan owó osù òsìsẹ́ nìkan láti ọwọ́ ìjoba.
Leave a Reply