Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí ń darí àpèjọ Ìgbìmọ̀ Aláse àpapọ̀ lọ́wọ́ báyìí lórí ayélujára ní Víllà, ní ìlú Àbújá.
Awọn ti o wa nibi ipade naa ni Akowe fun ijọba apapọ, Boss Mustapha, ọga agba fun awọn oṣiṣẹ Aarẹ, Ọjọgbọn Ibrahim Gambari ati ọga agba fun awọn oṣiṣẹ apapọ, Dokita Fọlaṣade Yẹmi-Ẹsan.



Awon minisita to tun wa nibẹ ni; Minisita fun Alaye ati Asa, Lai Mohammed, Iṣowo, Zainab Ahmed, Idajọ, Abubakar Malami, iṣẹ ati Ibugbe, Babatunde Fashọla ati ti olu-ilu, Mohammed Bello, ati awọn miiran.
Awọn minisita miiran n kopa lati awọn ọfiisi wọn kaakiri ni Abuja.

Ki ìpàdé náà tó bẹ̀rẹ̀,ṣe ìdákẹ́jẹ́ẹ́ ìṣẹ́jú kan lati fi bọlá fún Oloogbe Oyekunle Oluwasanmi tó jẹ́ minisita tẹ́lẹ̀, tó kú láìpẹ́ yìí ní ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́rin [85].
Oluwasanmi ṣiṣẹ fun orilẹ-ede gẹgẹ bi minisita Ipinlẹ fun Agbara ati Irin ni ọdun 1997.
Ó tún ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Alaga Ìgbìmọ̀ Aṣojú Ìròyìn Nàìjíríà,NAN, ní ọdún 1992.
Alaye lẹkunrẹrẹ nigba miran….
Leave a Reply