Ààrẹ ti ṣàlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ ìbọn yínyìn ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní agbègbè Dutsinma, ní ìpínlẹ̀ Katsina, mọ́ àwọn ọkọ̀ tí ó ń gbé àwọn ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ ààbo, ìlànà àti àwọn òṣìṣẹ́ oníròyìn ṣaájú Ààrẹ Mùhámmádù Bùhárí lọ sí Dàùrá fún ọdún iléyá gẹ́gẹ́ bí ìbànújẹ́ àti ìwà tí kòseé fààyè gbà.
Awọn onijagidijagan naa dabọn bo awọn ọkọ to n ba aarẹ rin naa lati ibi ti wọn ba si sugbọn awọn ọmọ ogun, olopaa ati awon oṣiṣẹ aabo orilẹ-ede,DSS ti wọn wa ninu awọn ọko naa paju da siwọn.
Ninu atẹjade kan, agbẹnusọ fun aarẹ, Garba Shehu sọ pe:
“Awọn eniyan meji ninu ọkọ awọn ẹṣọ naa n gba itọju fun ipalara diẹ. Gbogbo awọn oṣiṣẹ toku ati awọn ọkọ ayọkẹlẹ ni wọn gunlẹ si Daura layọ ati alaafia.
Leave a Reply