Hajj 2022: Ìpínlẹ̀ Kàdúná pàdánù arìnrìn àjò lọ sílẹ̀ mímọ́ méjì
Eyitayọ Fauziat Oyetunji
Àwọn arìnrìn àjò méjì láti ìjọba ìbílẹ̀ Igabi ní ìpínlẹ̀ Kàdúná, Àriwá Nàìjíríà, tí orúkọ wọn ń jẹ́ Yakubu Abdulsamad àti Haruna Suleiman ti jẹ́pè ọlọ́run.
Wọn jẹpe oluwa ni ọjọ Abamẹta ati Ọjọ Ajẹ lẹsẹẹsẹ ki wọn to gbera lọ si Saudi Arabia fun irin ajo mimọ.
Alukoro eto irin ajo mimọ, PO, tijọba ibilẹ, Aminu Surajo to kede iku wọn sọ pe won si ti sin awọn mejeeji gẹgẹ bi ilana Islam.
Awọn arinrin ajo ti o jẹpe oluwa naa ko ba wa lara awọn ipele akọkọ ti wọn yoo ko lọ si Saudi Arabia.
Nibayi, Gomina Ipinlẹ Kaduna, Dokita Hadiza Balarabe ti rọ awọn arinrin ajo ipele akọkọ ipinlẹ naa lati jẹ aṣoju rere ipinlẹ ati orilẹ-ede nigba ti wọn ba wa ni ilẹ mimọ.
Leave a Reply