Take a fresh look at your lifestyle.

Ẹgbẹ́ pè Fún Ìdábòbò Ọmọdé Áfíríkà

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 281

Àwọn tí ó níí ṣe pẹ̀lú ìdàgbàsókè ọmọdé, ti rọ àwọn òbí àti àwọn alágbàtọ́ láti tún ṣe ìgbìyànjú láti dáábòbò gbogbo ọmọ Áfíríkà nípa ṣíṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí àwọn ìṣe àṣà tí ó léwu àti àwọn ìwàkiwà tí ó  léwu fún àlàáfíà wọn bóyá ní báyìí tàbí ní ọjọ́ iwájú.

Wọn pe ipe yi nibi ayẹyẹ kan lati ṣe ayẹyẹ ayajọ ọjọ awọn ọmọde ilẹ Afirika ti ọdun 2022, eleyii ti akori rẹ: Imukuro awon iwa ti o lewu fun awọn ọmọde, ilosiwaju lori eto imulo ati iṣe lati odun 2013, to waye ni Ibadan, olu ilu ipinlẹ Ọyọ.

Eto naa ti ẹgbẹ oniroyin obinrin nipinlẹ Ọyọ, lorile-ede,(NAWOJ), ṣeto, pẹlu ajọṣepọ awọn ajọ miiran, ni awọn ọmọ ile-iwe , awọn obi, awọn olukọ, Awọn ẹgbẹ ti kii ṣe tijọba, awọn oluṣeto imulo, awọn aṣoju ijọba, awọn oloṣelu ati awọn ẹgbẹ ọdọ, laarin awon miran wa nijoko nibẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button