Take a fresh look at your lifestyle.

Kamẹrúùn: Ààrùn onígbá méjì gbẹ̀mí ọ̀gọ́ọ́rọ́ ènìyàn

Eyitayọ Fauziat Oyetunji

0 409

Ààrùn onígbá méjì ti tún padà sí orílè-èdè Kamẹrúùn,tí ó sì ti gbẹ̀mí  ènìyàn tí ó ju mẹ́rìnlé-láàdọ́je lọ láti Oṣù Kẹwàá, ọdún 2021, níbi tí àwọn ènìyàn igba-lé-lẹ́gbàajọ ti ní ààrùn náà,gẹ́gẹ́ bí àjọ ìsọ̀kan àgbáyé, UN ṣe sọ.

Titi di opin Oṣu karun un, “Ile-iṣẹ to n mojuto eto Ilera sọ pe, awọn eniyan ẹgbàárin ́-o -lé- ni- ọ̀kan -lé- ní- ojì-lé-nígba ni o ti ni aarun naa ti mẹrinle-laadọje si ti jẹpe oluwa ni orilẹ-ede naa,” gẹgẹ bi alaye kan lati ile-iṣẹ ajọ iṣọkan agbaye to n risi eto ọmọniyan, UN (Ocha).

Meje ninu awọn agbegbe mẹwa  lorile-ede Kamẹruun ni ajakalẹ-aarun naa kan. “Ẹkun Iwọ-oorun ti o jẹ eyiti o jẹ ibi ti ajakalẹ-aarun naa kan pupọ julọ ni awọn eniyan meéjìlá-dín-ní-ojì- lé- ní- ẹgbàáta-dín-ní-irinwó ti ko aarun naa ti aadọrin eniyan si ti jẹpe oluwa, agbegbe ti o tẹle ni Littoral, ti eniyan ẹ̀jọ- lé- ní- ẹgbẹ́ọ̀kànlá ti ko aarun naa ti eniyan meji-din-lọgọta si ti jepe oluwa”,Ọcha.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

button